Sefaniah 3:19
Zephaniah 3:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní àkókò náà ni èmi yóò dojúkọ àwọn tí ń ni yín lára, èmi yóò gba àtiro là, èmi yóò sì ṣa àwọn tí ó ti fọ́nká jọ, èmi yóò fi ìyìn àti ọlá fún wọn ní gbogbo ilẹ̀ tí a bá ti dójútì wọ́n.
Zephaniah 3:19 in English
Zephaniah 3:19 · Berean Standard Bible
Behold, at that time, I will deal with all who afflict you. I will save the lame and gather the scattered; and I will appoint praise and fame for the disgraced throughout the earth.
Context
17Olúwa Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ,
Ó ní agbára láti gbà ọ là.
Yóò yọ̀ ni orí rẹ fún ayọ̀;
Yóò tún ọ ṣe nínú ìfẹ́ rẹ̀,
Yóò sì fi orin yọ̀ ní orí rẹ.” 18“Èmi ó kó àwọn tí ó ń banújẹ́ fún àjọ̀dún tí a yàn jọ,
àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀;
àwọn tí ẹ̀gàn rẹ̀ jásí ẹ̀rù. 19Ní àkókò náà
ni èmi yóò dojúkọ àwọn
tí ń ni yín lára,
èmi yóò gba àtiro là,
èmi yóò sì ṣa àwọn tí ó ti fọ́nká jọ,
èmi yóò fi ìyìn àti ọlá fún wọn ní
gbogbo ilẹ̀ tí a bá ti dójútì wọ́n. 20Ní àkókò náà ni èmi yóò ṣà yín jọ;
nígbà náà ni èmi yóò mú un yín padà wá sílé.
Èmi yóò fi ọlá àti ìyìn fún un yín
láàrín gbogbo ènìyàn àgbáyé,
nígbà tí èmi yóò yí ìgbèkùn yín
padà bọ sípò ní ojú ara yín,”
ni Olúwa wí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.