Native Bible

Zephaniah 3:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ, Ó ní agbára láti gbà ọ là. Yóò yọ̀ ni orí rẹ fún ayọ̀; Yóò tún ọ ṣe nínú ìfẹ́ rẹ̀, Yóò sì fi orin yọ̀ ní orí rẹ.”

Zephaniah 3:17 in English

Zephaniah 3:17 · Berean Standard Bible

The LORD your God is among you; He is mighty to save. He will rejoice over you with gladness; He will quiet you with His love;* He will rejoice over you with singing.”

Context

15Olúwa ti mú ìdájọ́ rẹ wọ̀n-ọn-nì kúrò, ó sì ti ti àwọn ọ̀tá rẹ padà sẹ́yìn. Olúwa, ọba Israẹli wà pẹ̀lú rẹ; ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù ibi kan mọ́. 16Ní ọjọ́ náà, wọn yóò sọ fún Jerusalẹmu pé, “Má ṣe bẹ̀rù Sioni; má sì ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó dẹ̀. 17Olúwa Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ, Ó ní agbára láti gbà ọ là. Yóò yọ̀ ni orí rẹ fún ayọ̀; Yóò tún ọ ṣe nínú ìfẹ́ rẹ̀, Yóò sì fi orin yọ̀ ní orí rẹ.” 18“Èmi ó kó àwọn tí ó ń banújẹ́ fún àjọ̀dún tí a yàn jọ, àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀; àwọn tí ẹ̀gàn rẹ̀ jásí ẹ̀rù. 19Ní àkókò náà ni èmi yóò dojúkọ àwọn tí ń ni yín lára, èmi yóò gba àtiro là, èmi yóò sì ṣa àwọn tí ó ti fọ́nká jọ, èmi yóò fi ìyìn àti ọlá fún wọn ní gbogbo ilẹ̀ tí a bá ti dójútì wọ́n.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.