Native Bible

Zephaniah 3:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Èmi ó kó àwọn tí ó ń banújẹ́ fún àjọ̀dún tí a yàn jọ, àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀; àwọn tí ẹ̀gàn rẹ̀ jásí ẹ̀rù.

Zephaniah 3:18 in English

Zephaniah 3:18 · Berean Standard Bible

“I will gather those among you who grieve over the appointed feasts, so that you will no longer suffer reproach.

Context

16Ní ọjọ́ náà, wọn yóò sọ fún Jerusalẹmu pé, “Má ṣe bẹ̀rù Sioni; má sì ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó dẹ̀. 17Olúwa Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ, Ó ní agbára láti gbà ọ là. Yóò yọ̀ ni orí rẹ fún ayọ̀; Yóò tún ọ ṣe nínú ìfẹ́ rẹ̀, Yóò sì fi orin yọ̀ ní orí rẹ.” 18“Èmi ó kó àwọn tí ó ń banújẹ́ fún àjọ̀dún tí a yàn jọ, àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀; àwọn tí ẹ̀gàn rẹ̀ jásí ẹ̀rù. 19Ní àkókò náà ni èmi yóò dojúkọ àwọn tí ń ni yín lára, èmi yóò gba àtiro là, èmi yóò sì ṣa àwọn tí ó ti fọ́nká jọ, èmi yóò fi ìyìn àti ọlá fún wọn ní gbogbo ilẹ̀ tí a bá ti dójútì wọ́n. 20Ní àkókò náà ni èmi yóò ṣà yín jọ; nígbà náà ni èmi yóò mú un yín padà wá sílé. Èmi yóò fi ọlá àti ìyìn fún un yín láàrín gbogbo ènìyàn àgbáyé, nígbà tí èmi yóò yí ìgbèkùn yín padà bọ sípò ní ojú ara yín,” ni Olúwa wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.