Sefaniah 1:12
Zephaniah 1:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní àkókò wọ̀n-ọn-nì, èmi yóò wá Jerusalẹmu kiri pẹ̀lú fìtílà, èmi ó sì fi ìyà jẹ àwọn tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn, tí wọn sì dàbí àwọn ènìyàn tí ó sinmi sínú gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ wọn, àwọn tí wọn sì ń wí ní ọkàn wọn pé, ‘Olúwa kì yóò ṣe nǹkan kan tí ó jẹ́ rere tàbí tí ó jẹ́ búburú.’
Zephaniah 1:12 in English
Zephaniah 1:12 · Berean Standard Bible
And at that time I will search Jerusalem with lamps and punish the men settled in complacency,* who say to themselves, ‘The LORD will do nothing, either good or bad.’
Context
10“Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí,
“Ohùn ẹkún yóò wà láti ìhà ibodè ẹja,
híhu láti ìhà kejì wá àti
ariwo ńlá láti òkè kékeré wá. 11Ẹ hu, ẹ̀yin tí ń gbé ní agbègbè ọjà,
gbogbo àwọn oníṣòwò rẹ̀ ni a ó mú kúrò,
gbogbo àwọn ẹni tí ó ń ra fàdákà ni a ó sì parun. 12Ní àkókò wọ̀n-ọn-nì, èmi yóò wá Jerusalẹmu kiri pẹ̀lú fìtílà,
èmi ó sì fi ìyà jẹ àwọn tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn,
tí wọn sì dàbí àwọn ènìyàn tí ó sinmi sínú gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ wọn,
àwọn tí wọn sì ń wí ní ọkàn wọn pé, ‘Olúwa kì yóò ṣe nǹkan kan
tí ó jẹ́ rere tàbí tí ó jẹ́ búburú.’ 13Nítorí náà, ọrọ̀ wọn yóò di ìkógun,
àti ilé wọn yóò sì run.
Àwọn yóò sì kọ́ ilé pẹ̀lú,
ṣùgbọ́n wọn kì yóò gbé nínú ilé náà,
wọn yóò gbin ọgbà àjàrà,
ṣùgbọ́n wọn kì yóò mu ọtí
wáìnì láti inú rẹ̀.” 14“Ọjọ́ ńlá Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀,
ó kù sí dẹ̀dẹ̀ ó sì ń yára bọ̀ kánkán.
Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ohùn ẹkún àwọn alágbára;
ní ọjọ́ Olúwa yóò korò púpọ̀,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.