Native Bible

Zephaniah 1:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ọjọ́ ńlá Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀, ó kù sí dẹ̀dẹ̀ ó sì ń yára bọ̀ kánkán. Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ohùn ẹkún àwọn alágbára; ní ọjọ́ Olúwa yóò korò púpọ̀,

Zephaniah 1:14 in English

Zephaniah 1:14 · Berean Standard Bible

The great Day of the LORD is near— near and coming quickly. Listen, the Day of the LORD! Then the cry of the mighty will be bitter.

Context

12Ní àkókò wọ̀n-ọn-nì, èmi yóò wá Jerusalẹmu kiri pẹ̀lú fìtílà, èmi ó sì fi ìyà jẹ àwọn tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn, tí wọn sì dàbí àwọn ènìyàn tí ó sinmi sínú gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ wọn, àwọn tí wọn sì ń wí ní ọkàn wọn pé, ‘Olúwa kì yóò ṣe nǹkan kan tí ó jẹ́ rere tàbí tí ó jẹ́ búburú.’ 13Nítorí náà, ọrọ̀ wọn yóò di ìkógun, àti ilé wọn yóò sì run. Àwọn yóò sì kọ́ ilé pẹ̀lú, ṣùgbọ́n wọn kì yóò gbé nínú ilé náà, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, ṣùgbọ́n wọn kì yóò mu ọtí wáìnì láti inú rẹ̀.” 14“Ọjọ́ ńlá Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀, ó kù sí dẹ̀dẹ̀ ó sì ń yára bọ̀ kánkán. Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ohùn ẹkún àwọn alágbára; ní ọjọ́ Olúwa yóò korò púpọ̀, 15ọjọ́ náà yóò jẹ́ ọjọ́ ìbínú, ọjọ́ ìrora àti ìpọ́njú, ọjọ́ òfò àti idà ọjọ́ ìdahoro ọjọ́ òkùnkùn àti ìtẹ̀ba, ọjọ́ kurukuru àti òkùnkùn biribiri, 16ọjọ́ ìpè àti ìpè ogun sí àwọn ìlú olódi àti sí àwọn ilé ìṣọ́ gíga.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.