Native Bible

Zechariah 6:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àti àwọn ẹṣin funfun ní kẹ̀kẹ́ ẹ̀kẹta; àti àwọn adíkálà àti alágbára ẹṣin ní kẹ̀kẹ́ ẹ̀kẹrin.

Zechariah 6:3 in English

Zechariah 6:3 · Berean Standard Bible

the third white horses, and the fourth dappled horses—all of them strong.

Context

1Mo sì yípadà, mo sì gbé ojú mi sókè, mo sì wò, sì kíyèsi i, kẹ̀kẹ́ mẹ́rin jáde wá láti àárín òkè ńlá méjì, àwọn òkè ńlá náà sì jẹ́ òkè ńlá idẹ. 2Àwọn ẹṣin pupa wà ní kẹ̀kẹ́ èkínní; àti àwọn ẹṣin dúdú ní kẹ̀kẹ́ èkejì. 3Àti àwọn ẹṣin funfun ní kẹ̀kẹ́ ẹ̀kẹta; àti àwọn adíkálà àti alágbára ẹṣin ní kẹ̀kẹ́ ẹ̀kẹrin. 4Mo sì dáhùn, mo sì béèrè lọ́wọ́ angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Kí ni ìwọ̀nyí, olúwa mi.” 5Angẹli náà si dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀mí mẹ́rin ti ọ̀run, tí wọn ń lọ kúrò lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ara wọn hàn níwájú Olúwa gbogbo ayé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.