Native Bible

Zechariah 6:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Angẹli náà si dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀mí mẹ́rin ti ọ̀run, tí wọn ń lọ kúrò lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ara wọn hàn níwájú Olúwa gbogbo ayé.

Zechariah 6:5 in English

Zechariah 6:5 · Berean Standard Bible

And the angel told me, “These are the four spirits * of heaven, going forth from their station before the Lord of all the earth.

Context

3Àti àwọn ẹṣin funfun ní kẹ̀kẹ́ ẹ̀kẹta; àti àwọn adíkálà àti alágbára ẹṣin ní kẹ̀kẹ́ ẹ̀kẹrin. 4Mo sì dáhùn, mo sì béèrè lọ́wọ́ angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Kí ni ìwọ̀nyí, olúwa mi.” 5Angẹli náà si dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀mí mẹ́rin ti ọ̀run, tí wọn ń lọ kúrò lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ara wọn hàn níwájú Olúwa gbogbo ayé. 6Àwọn ẹṣin dúdú tí ó wà nínú rẹ̀ jáde lọ sí ilẹ̀ àríwá; àwọn funfun sì jáde lọ si ìwọ̀-oòrùn; àwọn adíkálà sì jáde lọ sí ìhà ilẹ̀ gúúsù.” 7Àwọn alágbára ẹṣin sì jáde lọ, wọ́n sì ń wá ọ̀nà àti lọ kí wọn bá a lè rìn síyìn-ín sọ́hùn-ún ni ayé; ó sì wí pé, “Ẹ lọ, ẹ lọ rìn síyìn-ín sọ́hùn-ún ní ayé!” Wọ́n sì rín síyìn-ín sọ́hùn-ún ní ayé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.