Sekariah 6:7
Zechariah 6:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn alágbára ẹṣin sì jáde lọ, wọ́n sì ń wá ọ̀nà àti lọ kí wọn bá a lè rìn síyìn-ín sọ́hùn-ún ni ayé; ó sì wí pé, “Ẹ lọ, ẹ lọ rìn síyìn-ín sọ́hùn-ún ní ayé!” Wọ́n sì rín síyìn-ín sọ́hùn-ún ní ayé.
Zechariah 6:7 in English
Zechariah 6:7 · Berean Standard Bible
As the strong horses went out, they were eager to go and patrol the earth; and the LORD said, “Go and patrol the earth.” So they patrolled the earth.
Context
5Angẹli náà si dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀mí mẹ́rin ti ọ̀run, tí wọn ń lọ kúrò lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ara wọn hàn níwájú Olúwa gbogbo ayé. 6Àwọn ẹṣin dúdú tí ó wà nínú rẹ̀ jáde lọ sí ilẹ̀ àríwá; àwọn funfun sì jáde lọ si ìwọ̀-oòrùn; àwọn adíkálà sì jáde lọ sí ìhà ilẹ̀ gúúsù.” 7Àwọn alágbára ẹṣin sì jáde lọ, wọ́n sì ń wá ọ̀nà àti lọ kí wọn bá a lè rìn síyìn-ín sọ́hùn-ún ni ayé; ó sì wí pé, “Ẹ lọ, ẹ lọ rìn síyìn-ín sọ́hùn-ún ní ayé!” Wọ́n sì rín síyìn-ín sọ́hùn-ún ní ayé. 8Nígbà náà ni ohùn kan sì ké sí mi, ó sì bá mi sọ̀rọ̀ wí pé, “Wò ó, àwọn wọ̀nyí tí ó lọ síhà ilẹ̀ àríwá ti mú ẹ̀mí mi parọ́rọ́ ni ilẹ̀ àríwá.” 9Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé:
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.