Sekariah 14:6
Zechariah 14:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, ìmọ́lẹ̀ kì yóò mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ṣókùnkùn.
Zechariah 14:6 in English
Zechariah 14:6 · Berean Standard Bible
On that day there will be no light, no cold or frost.
Context
4Ẹsẹ̀ rẹ̀ yóò sì dúró ni ọjọ́ náà lórí òkè Olifi, tí ó wà níwájú Jerusalẹmu ni ìlà-oòrùn, òkè Olifi yóò sì là á sí méjì, sí ìhà ìlà-oòrùn àti ìhà ìwọ̀-oòrùn, àfonífojì ńlá ńlá yóò wà: ìdajì òkè náà yóò sì ṣí síhà àríwá, àti ìdajì rẹ̀ síhà gúúsù. 5Ẹ̀yin ó sì sá sí àfonífojì àwọn òkè mi, nítorí pé àfonífojì òkè náà yóò dé Aseli: nítòótọ́, ẹ̀yin ó sá bí ẹ tí sá fún ìmìmì-ilẹ̀ ni ọjọ́ Ussiah ọba Juda: Olúwa Ọlọ́run mi yóò sì wá, àti gbogbo àwọn Ẹni mímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. 6Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, ìmọ́lẹ̀ kì yóò mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ṣókùnkùn. 7Ṣùgbọ́n yóò jẹ́ ọjọ́ kan mímọ́ fún Olúwa, kì í ṣe ọ̀sán, kì í ṣe òru; ṣùgbọ́n yóò ṣe pé, ni àṣálẹ́ ìmọ́lẹ̀ yóò wà. 8Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, omi ìyè yóò tí Jerusalẹmu sàn lọ; ìdajì wọn síhà Òkun ìlà-oòrùn, àti ìdajì wọn síhà okùn ẹ̀yìn: nígbà ẹ̀rùn àti nígbà òtútù ni yóò rí bẹ́ẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.