Native Bible

Zechariah 14:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹsẹ̀ rẹ̀ yóò sì dúró ni ọjọ́ náà lórí òkè Olifi, tí ó wà níwájú Jerusalẹmu ni ìlà-oòrùn, òkè Olifi yóò sì là á sí méjì, sí ìhà ìlà-oòrùn àti ìhà ìwọ̀-oòrùn, àfonífojì ńlá ńlá yóò wà: ìdajì òkè náà yóò sì ṣí síhà àríwá, àti ìdajì rẹ̀ síhà gúúsù.

Zechariah 14:4 in English

Zechariah 14:4 · Berean Standard Bible

On that day His feet will stand on the Mount of Olives, east of Jerusalem, and the Mount of Olives will be split in two from east to west, forming a great valley, with half the mountain moving to the north and half to the south.

Context

2Nítorí èmi ó kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí Jerusalẹmu fún ogun; a ó sì ko ìlú náà, a ó sì kó àwọn ilé, a ó sì ba àwọn obìnrin jẹ́, ààbọ̀ ìlú náà yóò lọ sí ìgbèkùn, a kì yóò sì gé ìyókù àwọn ènìyàn náà kúrò ni ìlú náà. 3Nígbà náà ni Olúwa yóò jáde lọ, yóò sì bá àwọn orílẹ̀-èdè náà jà, gẹ́gẹ́ bí í ti ìjà ní ọjọ́ ogun. 4Ẹsẹ̀ rẹ̀ yóò sì dúró ni ọjọ́ náà lórí òkè Olifi, tí ó wà níwájú Jerusalẹmu ni ìlà-oòrùn, òkè Olifi yóò sì là á sí méjì, sí ìhà ìlà-oòrùn àti ìhà ìwọ̀-oòrùn, àfonífojì ńlá ńlá yóò wà: ìdajì òkè náà yóò sì ṣí síhà àríwá, àti ìdajì rẹ̀ síhà gúúsù. 5Ẹ̀yin ó sì sá sí àfonífojì àwọn òkè mi, nítorí pé àfonífojì òkè náà yóò dé Aseli: nítòótọ́, ẹ̀yin ó sá bí ẹ tí sá fún ìmìmì-ilẹ̀ ni ọjọ́ Ussiah ọba Juda: Olúwa Ọlọ́run mi yóò sì wá, àti gbogbo àwọn Ẹni mímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. 6Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, ìmọ́lẹ̀ kì yóò mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ṣókùnkùn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.