Sekariah 1:10
Zechariah 1:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọkùnrin tí ó dúró láàrín àwọn igi maritili sì dáhùn ó sì wí pé, “Wọ̀nyí ní àwọn tí Olúwa ti rán láti máa rìn sókè sódò ni ayé.”
Zechariah 1:10 in English
Zechariah 1:10 · Berean Standard Bible
Then the man standing among the myrtle trees explained, “They are the ones the LORD has sent to patrol the earth.”
Context
8Mo rí ìran kan ni òru, si wò ó, ọkùnrin kan ń gun ẹṣin pupa kan, òun sì dúró láàrín àwọn igi maritili tí ó wà ní ibi òòji; lẹ́yìn rẹ̀ sì ni ẹṣin pupa, adíkálà, àti funfun gbé wà. 9Nígbà náà ni mo wí pé, “Kí ni wọ̀nyí olúwa mi?”
Angẹli tí ń ba mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, “Èmi ó fi ohun tí àwọn wọ̀nyí jẹ́ hàn ọ́.” 10Ọkùnrin tí ó dúró láàrín àwọn igi maritili sì dáhùn ó sì wí pé, “Wọ̀nyí ní àwọn tí Olúwa ti rán láti máa rìn sókè sódò ni ayé.” 11Wọ́n si dá angẹli Olúwa tí ó dúró láàrín àwọn igi maritili náà lóhùn pé, “Àwa ti rìn sókè sódò já ayé, àwa sí ti rí i pé gbogbo ayé wà ní ìsinmi àti àlàáfíà.” 12Nígbà náà ni angẹli Olúwa náà dáhùn ó sì wí pé, “Olúwa àwọn ọmọ-ogun, yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ kì yóò fi ṣàánú fún Jerusalẹmu, àti fún àwọn ìlú ńlá Juda, ti ìwọ ti bínú sí ni àádọ́rin ọdún wọ̀nyí?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.