Native Bible

Zechariah 1:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni angẹli Olúwa náà dáhùn ó sì wí pé, “Olúwa àwọn ọmọ-ogun, yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ kì yóò fi ṣàánú fún Jerusalẹmu, àti fún àwọn ìlú ńlá Juda, ti ìwọ ti bínú sí ni àádọ́rin ọdún wọ̀nyí?”

Zechariah 1:12 in English

Zechariah 1:12 · Berean Standard Bible

Then the angel of the LORD said, “How long, O LORD of Hosts, will You withhold mercy from Jerusalem and the cities of Judah, with which You have been angry these seventy years?”

Context

10Ọkùnrin tí ó dúró láàrín àwọn igi maritili sì dáhùn ó sì wí pé, “Wọ̀nyí ní àwọn tí Olúwa ti rán láti máa rìn sókè sódò ni ayé.” 11Wọ́n si dá angẹli Olúwa tí ó dúró láàrín àwọn igi maritili náà lóhùn pé, “Àwa ti rìn sókè sódò já ayé, àwa sí ti rí i pé gbogbo ayé wà ní ìsinmi àti àlàáfíà.” 12Nígbà náà ni angẹli Olúwa náà dáhùn ó sì wí pé, “Olúwa àwọn ọmọ-ogun, yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ kì yóò fi ṣàánú fún Jerusalẹmu, àti fún àwọn ìlú ńlá Juda, ti ìwọ ti bínú sí ni àádọ́rin ọdún wọ̀nyí?” 13Olúwa sì fi ọ̀rọ̀ rere àti ọ̀rọ̀ ìtùnú dá angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ lóhùn. 14Angẹli ti ń bá mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, “Ìwọ kígbe wí pé, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Èmi ń fi ìjowú ńlá jowú fún Jerusalẹmu àti fún Sioni.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.