Native Bible

Zechariah 1:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mo rí ìran kan ni òru, si wò ó, ọkùnrin kan ń gun ẹṣin pupa kan, òun sì dúró láàrín àwọn igi maritili tí ó wà ní ibi òòji; lẹ́yìn rẹ̀ sì ni ẹṣin pupa, adíkálà, àti funfun gbé wà.

Zechariah 1:8 in English

Zechariah 1:8 · Berean Standard Bible

I looked out into the night and saw a man riding on a red horse. He was standing among the myrtle trees in the hollow, and behind him were red, sorrel, and white horses.

Context

6Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi àti ìlànà mi, ti mo pa ní àṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì, kò ha tún bá àwọn baba yín? “Wọ́n sì padà wọ́n wí pé, ‘Gẹ́gẹ́ bí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti rò láti ṣe sí wa, gẹ́gẹ́ bi ọ̀nà wa, àti gẹ́gẹ́ bí ìṣe wa, bẹ́ẹ̀ ní o ti ṣe sí wa.’ ” 7Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kọkànlá, tí ó jẹ́, oṣù Sebati, ní ọdún kejì Dariusi, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ wòlíì Sekariah, ọmọ Berekiah ọmọ Iddo wá, pé. 8Mo rí ìran kan ni òru, si wò ó, ọkùnrin kan ń gun ẹṣin pupa kan, òun sì dúró láàrín àwọn igi maritili tí ó wà ní ibi òòji; lẹ́yìn rẹ̀ sì ni ẹṣin pupa, adíkálà, àti funfun gbé wà. 9Nígbà náà ni mo wí pé, “Kí ni wọ̀nyí olúwa mi?” Angẹli tí ń ba mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, “Èmi ó fi ohun tí àwọn wọ̀nyí jẹ́ hàn ọ́.” 10Ọkùnrin tí ó dúró láàrín àwọn igi maritili sì dáhùn ó sì wí pé, “Wọ̀nyí ní àwọn tí Olúwa ti rán láti máa rìn sókè sódò ni ayé.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.