Native Bible

Titus 3:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ènìyàn nílò láti kọ́ bí a tí ń fi ara ẹni jì sí iṣẹ́ rere kí wọn ba à le pèsè ohun kòsémánìí fún ara wọn, nípa èyí, wọn kì yóò jẹ́ aláìléso.

Titus 3:14 in English

Titus 3:14 · Berean Standard Bible

And our people must also learn to devote themselves to good works in order to meet the pressing needs of others, so that they will not be unfruitful.

Context

12Ní kété tí mo bá ti rán Artema tàbí Tikiku sí ọ, sa gbogbo ipá rẹ láti tọ̀ mí wá ní Nikopoli, nítorí mo ti pinnu láti lo ìgbà òtútù mi níbẹ̀. 13Sa gbogbo agbára rẹ láti ran Senasi amòfin àti Apollo lọ́wọ́ nínú ìrìnàjò wọn. Rí i dájú pé wọ́n ní ohun gbogbo tí wọn nílò. 14Àwọn ènìyàn nílò láti kọ́ bí a tí ń fi ara ẹni jì sí iṣẹ́ rere kí wọn ba à le pèsè ohun kòsémánìí fún ara wọn, nípa èyí, wọn kì yóò jẹ́ aláìléso. 15Gbogbo àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ mi kí ọ. Bá mi kí àwọn tí ó fẹ́ wa nínú ìgbàgbọ́. Kí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú gbogbo yín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.