Titu 3:13
Titus 3:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Sa gbogbo agbára rẹ láti ran Senasi amòfin àti Apollo lọ́wọ́ nínú ìrìnàjò wọn. Rí i dájú pé wọ́n ní ohun gbogbo tí wọn nílò.
Titus 3:13 in English
Titus 3:13 · Berean Standard Bible
Do your best to equip Zenas the lawyer and Apollos, so that they will have everything they need.
Context
11Kí ó dá ọ lójú wí pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti yapa, ó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, ó sì dá ara rẹ̀ lẹ́bi. 12Ní kété tí mo bá ti rán Artema tàbí Tikiku sí ọ, sa gbogbo ipá rẹ láti tọ̀ mí wá ní Nikopoli, nítorí mo ti pinnu láti lo ìgbà òtútù mi níbẹ̀. 13Sa gbogbo agbára rẹ láti ran Senasi amòfin àti Apollo lọ́wọ́ nínú ìrìnàjò wọn. Rí i dájú pé wọ́n ní ohun gbogbo tí wọn nílò. 14Àwọn ènìyàn nílò láti kọ́ bí a tí ń fi ara ẹni jì sí iṣẹ́ rere kí wọn ba à le pèsè ohun kòsémánìí fún ara wọn, nípa èyí, wọn kì yóò jẹ́ aláìléso. 15Gbogbo àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ mi kí ọ.
Bá mi kí àwọn tí ó fẹ́ wa nínú ìgbàgbọ́.
Kí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú gbogbo yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.