Romu 15:22
Romans 15:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìdí nìyìí tí ààyè fi há pẹ́ tó bẹ́ẹ̀ fún mi kí n tó tọ̀ yín wa.
Romans 15:22 in English
Romans 15:22 · Berean Standard Bible
That is why I have often been hindered from coming to you.
Context
20Ó jẹ́ èrò mi ní gbogbo ìgbà láti wàásù ìyìnrere Kristi ní ibi gbogbo tí wọn kò tí ì mọ̀ ọ́n, kí èmi kí ó má ṣe máa mọ àmọlé lórí ìpìlẹ̀ ẹlòmíràn. 21Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:
“Àwọn ẹni tí a kò tí ì sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún yóò rí i,
àti àwọn tí kò tí ì gbọ́, òye yóò sì yé.” 22Ìdí nìyìí tí ààyè fi há pẹ́ tó bẹ́ẹ̀ fún mi kí n tó tọ̀ yín wa. 23Ṣùgbọ́n báyìí tí kò tún sí ibòmíràn fún mi mọ́ láti ṣiṣẹ́ ní ẹkùn yìí, tí èmi sì ti ń pòǹgbẹ láti ọdún púpọ̀ sẹ́yìn láti bẹ́ yín wò, 24mo gbèrò láti ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí mo bá lọ sí Spania. Èmi yóò rí i yín ní ọ̀nà àjò mi, àti pé ẹ ó mú mi já ọ̀nà níbẹ̀ láti ọ̀dọ̀ yín lọ, lẹ́yìn tí mo bá gbádùn ẹgbẹ́ yín fún ìgbà díẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.