Romu 15:21
Romans 15:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Àwọn ẹni tí a kò tí ì sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún yóò rí i, àti àwọn tí kò tí ì gbọ́, òye yóò sì yé.”
Romans 15:21 in English
Romans 15:21 · Berean Standard Bible
Rather, as it is written: “Those who were not told about Him will see, and those who have not heard will understand.”*
Context
19nípa agbára iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu, nípa agbára Ẹ̀mí Ọlọ́run, tó bẹ́ẹ̀ láti Jerusalẹmu àti yíkákiri, àní títí fi dé Illirikoni, mo ti polongo ìyìnrere Kristi ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. 20Ó jẹ́ èrò mi ní gbogbo ìgbà láti wàásù ìyìnrere Kristi ní ibi gbogbo tí wọn kò tí ì mọ̀ ọ́n, kí èmi kí ó má ṣe máa mọ àmọlé lórí ìpìlẹ̀ ẹlòmíràn. 21Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:
“Àwọn ẹni tí a kò tí ì sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún yóò rí i,
àti àwọn tí kò tí ì gbọ́, òye yóò sì yé.” 22Ìdí nìyìí tí ààyè fi há pẹ́ tó bẹ́ẹ̀ fún mi kí n tó tọ̀ yín wa. 23Ṣùgbọ́n báyìí tí kò tún sí ibòmíràn fún mi mọ́ láti ṣiṣẹ́ ní ẹkùn yìí, tí èmi sì ti ń pòǹgbẹ láti ọdún púpọ̀ sẹ́yìn láti bẹ́ yín wò,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.