Romu 11:7
Romans 11:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí ha ni? Ohun tí Israẹli ń wá kiri, òun náà ni kò rí; ṣùgbọ́n àwọn ẹni àyànfẹ́ ti rí i, a sì sé àyà àwọn ìyókù le.
Romans 11:7 in English
Romans 11:7 · Berean Standard Bible
What then? What Israel was seeking, it failed to obtain, but the elect did. The others were hardened,
Context
5Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni, ní àkókò yìí àṣẹ́kù àwọn ènìyàn kan wà nípa ìyànfẹ́ ti oore-ọ̀fẹ́. 6Bí ó bá sì ṣe pé nípa ti oore-ọ̀fẹ́ ni, ǹjẹ́ kì í ṣe ti iṣẹ́ mọ́; bí bẹ́ẹ̀ kọ́ oore-ọ̀fẹ́ kì yóò jẹ́ oore-ọ̀fẹ́ mọ́. Ṣùgbọ́n bí ó ṣe pé nípa ti iṣẹ́ ni, ǹjẹ́ kì í ṣe ti oore-ọ̀fẹ́ mọ́; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, iṣẹ́ kì í ṣe iṣẹ́ mọ́. 7Kí ha ni? Ohun tí Israẹli ń wá kiri, òun náà ni kò rí; ṣùgbọ́n àwọn ẹni àyànfẹ́ ti rí i, a sì sé àyà àwọn ìyókù le. 8Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:
“Ọlọ́run ti fún wọn ní ẹ̀mí oorun,
àwọn ojú tí kò le ríran
àti àwọn etí tí kò le gbọ́rọ̀,
títí ó fi di òní olónìí yìí.” 9Dafidi sì wí pé:
“Jẹ́ kí tábìlì wọn kí ó di ìdẹ̀kùn àti tàkúté,
ohun ìkọ̀sẹ̀ àti ẹ̀san fún wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.