Native Bible

Romans 11:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Dafidi sì wí pé: “Jẹ́ kí tábìlì wọn kí ó di ìdẹ̀kùn àti tàkúté, ohun ìkọ̀sẹ̀ àti ẹ̀san fún wọn.

Romans 11:9 in English

Romans 11:9 · Berean Standard Bible

And David says: “May their table become a snare and a trap, a stumbling block and a retribution to them.

Context

7Kí ha ni? Ohun tí Israẹli ń wá kiri, òun náà ni kò rí; ṣùgbọ́n àwọn ẹni àyànfẹ́ ti rí i, a sì sé àyà àwọn ìyókù le. 8Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Ọlọ́run ti fún wọn ní ẹ̀mí oorun, àwọn ojú tí kò le ríran àti àwọn etí tí kò le gbọ́rọ̀, títí ó fi di òní olónìí yìí.” 9Dafidi sì wí pé: “Jẹ́ kí tábìlì wọn kí ó di ìdẹ̀kùn àti tàkúté, ohun ìkọ̀sẹ̀ àti ẹ̀san fún wọn. 10Jẹ́ kí ojú wọn ṣókùnkùn, kí wọn kí ó má le ríran, Kí wọn kí ó sì tẹ ẹ̀yìn wọn ba nígbà gbogbo.” 11Ǹjẹ́ mo ní, wọ́n ha kọsẹ̀ kí wọn kí ó lè ṣubú? Kí a má ri i, ṣùgbọ́n nípa ìṣubú wọn, ìgbàlà dé ọ̀dọ̀ àwọn Kèfèrí, láti mú Israẹli jowú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.