Native Bible

Revelation 7:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

wí pé, “Ẹ má ṣe pa ayé, tàbí Òkun, tàbí igi lára, títí àwa ó fi fi èdìdì sàmì sí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa ní iwájú wọn.”

Revelation 7:3 in English

Revelation 7:3 · Berean Standard Bible

“Do not harm the land or sea or trees until we have sealed the foreheads of the servants of our God.”

Context

1Lẹ́yìn èyí ni mo rí angẹli mẹ́rin dúró ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, wọ́n di afẹ́fẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé mú, kí ó má ṣe fẹ́ sórí ilẹ̀, tàbí sórí Òkun, tàbí sára igikígi. 2Mo sì rí angẹli mìíràn tí ó ń ti ìhà ìlà-oòrùn gòkè wá, ti òun ti èdìdì Ọlọ́run alààyè lọ́wọ́ rẹ. Ó sì kígbe ní ohùn rara sí àwọn angẹli mẹ́rin náà tí a fi fún un láti pa ayé, àti Òkun, lára, 3wí pé, “Ẹ má ṣe pa ayé, tàbí Òkun, tàbí igi lára, títí àwa ó fi fi èdìdì sàmì sí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa ní iwájú wọn.” 4Mo sì gbọ́ iye àwọn tí a fi èdìdì sàmì si, àwọn tí a sàmì sí jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) láti inú gbogbo ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli wá. 5Láti inú ẹ̀yà Juda a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000). Láti inú ẹ̀yà Reubeni a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000). Láti inú ẹ̀yà Gadi a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000).

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.