Native Bible

Revelation 7:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Láti inú ẹ̀yà Juda a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000). Láti inú ẹ̀yà Reubeni a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000). Láti inú ẹ̀yà Gadi a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000).

Revelation 7:5 in English

Revelation 7:5 · Berean Standard Bible

From the tribe of Judah 12,000 were sealed, from the tribe of Reuben 12,000, from the tribe of Gad 12,000,

Context

3wí pé, “Ẹ má ṣe pa ayé, tàbí Òkun, tàbí igi lára, títí àwa ó fi fi èdìdì sàmì sí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa ní iwájú wọn.” 4Mo sì gbọ́ iye àwọn tí a fi èdìdì sàmì si, àwọn tí a sàmì sí jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) láti inú gbogbo ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli wá. 5Láti inú ẹ̀yà Juda a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000). Láti inú ẹ̀yà Reubeni a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000). Láti inú ẹ̀yà Gadi a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000). 6Láti inú ẹ̀yà Aṣeri a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000). Láti inú ẹ̀yà Naftali a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000). Láti inú ẹ̀yà Manase a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000). 7Láti inú ẹ̀yà Simeoni a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000). Láti inú ẹ̀yà Lefi a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000). Láti inú ẹ̀yà Isakari a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000).

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.