Ìfihàn 7:2
Revelation 7:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo sì rí angẹli mìíràn tí ó ń ti ìhà ìlà-oòrùn gòkè wá, ti òun ti èdìdì Ọlọ́run alààyè lọ́wọ́ rẹ. Ó sì kígbe ní ohùn rara sí àwọn angẹli mẹ́rin náà tí a fi fún un láti pa ayé, àti Òkun, lára,
Revelation 7:2 in English
Revelation 7:2 · Berean Standard Bible
And I saw another angel ascending from the east, with the seal of the living God. And he called out in a loud voice to the four angels who had been given power to harm the land and the sea:
Context
1Lẹ́yìn èyí ni mo rí angẹli mẹ́rin dúró ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, wọ́n di afẹ́fẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé mú, kí ó má ṣe fẹ́ sórí ilẹ̀, tàbí sórí Òkun, tàbí sára igikígi. 2Mo sì rí angẹli mìíràn tí ó ń ti ìhà ìlà-oòrùn gòkè wá, ti òun ti èdìdì Ọlọ́run alààyè lọ́wọ́ rẹ. Ó sì kígbe ní ohùn rara sí àwọn angẹli mẹ́rin náà tí a fi fún un láti pa ayé, àti Òkun, lára, 3wí pé, “Ẹ má ṣe pa ayé, tàbí Òkun, tàbí igi lára, títí àwa ó fi fi èdìdì sàmì sí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa ní iwájú wọn.” 4Mo sì gbọ́ iye àwọn tí a fi èdìdì sàmì si, àwọn tí a sàmì sí jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) láti inú gbogbo ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli wá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.