Native Bible

Revelation 7:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n sì kígbe ní ohùn rara, wí pé: “Ìgbàlà ni ti Ọlọ́run wá tí o jókòó lórí ìtẹ́, àti ti Ọ̀dọ́-àgùntàn!”

Revelation 7:10 in English

Revelation 7:10 · Berean Standard Bible

And they cried out in a loud voice: “Salvation to our God, who sits on the throne, and to the Lamb!”

Context

8Láti inú ẹ̀yà Sebuluni, a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000). Láti inú ẹ̀yà Josẹfu a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000). Láti inú ẹ̀yà Benjamini a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000). 9Lẹ́yìn náà, mo ri, sì kíyèsi i, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí ẹnikẹ́ni kò lè kà, láti inú orílẹ̀-èdè gbogbo, àti ẹ̀yà, àti ènìyàn, àti láti inú èdè gbogbo wá, wọn dúró níwájú ìtẹ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà, a wọ̀ wọ́n ni aṣọ funfun, imọ̀ ọ̀pẹ si ń bẹ ni ọwọ́ wọn. 10Wọ́n sì kígbe ní ohùn rara, wí pé: “Ìgbàlà ni ti Ọlọ́run wá tí o jókòó lórí ìtẹ́, àti ti Ọ̀dọ́-àgùntàn!” 11Gbogbo àwọn angẹli sì dúró yí ìtẹ́ náà ká, àti yí àwọn àgbà àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà ká, wọn wólẹ̀ wọn si dojúbolẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà wọ́n sì sin Ọlọ́run. 12Wí pe: “Àmín! Ìbùkún, àti ògo, àti ọgbọ́n, àti ọpẹ́, àti ọlá, àti agbára àti ipá fún Ọlọ́run wa láé àti láéláé! Àmín!”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.