Ìfihàn 20:7
Revelation 20:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún náà bá sì pé, a ó tú Satani sílẹ̀ kúrò nínú túbú rẹ̀.
Revelation 20:7 in English
Revelation 20:7 · Berean Standard Bible
When the thousand years are complete, Satan will be released from his prison,
Context
5(Àwọn òkú ìyókù kò wà láààyè mọ́ títí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún náà yóò fi pé). Èyí ni àjíǹde èkínní. 6Ẹni ìbùkún àti mímọ́ ni ẹni tí ó ní ipa nínú àjíǹde èkínní náà. Lórí àwọn wọ̀nyí ikú ẹ̀ẹ̀kejì kò ní agbára, ṣùgbọ́n wọn ó jẹ́ àlùfáà Ọlọ́run àti ti Kristi, wọn ó sì máa jẹ ọba pẹ̀lú rẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún. 7Nígbà tí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún náà bá sì pé, a ó tú Satani sílẹ̀ kúrò nínú túbú rẹ̀. 8Yóò sì jáde lọ láti máa tan àwọn orílẹ̀-èdè tí ń bẹ ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé jẹ, Gogu àti Magogu, láti gbá wọn jọ sí ogun: àwọn tí iyè wọn dàbí iyanrìn Òkun. 9Wọ́n sì gòkè lọ la ibú ayé já, wọ́n sì yí ibùdó àwọn ènìyàn mímọ́ ká àti ìlú àyànfẹ́ náà: iná sì ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, ó sì jó wọn run.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.