Native Bible

Revelation 15:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lẹ́yìn náà mo sì wo, sì kíyèsi i, a ṣí tẹmpili àgọ́ ẹ̀rí ní ọ̀run sílẹ̀;

Revelation 15:5 in English

Revelation 15:5 · Berean Standard Bible

After this I looked, and the temple—the tabernacle of the Testimony—was opened in heaven.

Context

3Wọ́n sì ń kọ orin ti Mose, ìránṣẹ́ Ọlọ́run, àti orin ti Ọ̀dọ́-Àgùntàn, wí pé: “Títóbi àti ìyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ, Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè; òdodo àti òtítọ́ ni ọ̀nà rẹ̀, ìwọ ọba àwọn orílẹ̀-èdè. 4Ta ni kì yóò bẹ̀rù, Olúwa, tí kì yóò sì fi ògo fún orúkọ rẹ̀? Nítorí ìwọ nìkan ṣoṣo ni mímọ́. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni yóò sì wá, ti yóò sì foríbalẹ̀ níwájú rẹ, nítorí a ti fi ìdájọ́ rẹ hàn.” 5Lẹ́yìn náà mo sì wo, sì kíyèsi i, a ṣí tẹmpili àgọ́ ẹ̀rí ní ọ̀run sílẹ̀; 6àwọn angẹli méje náà sì ti inú tẹmpili jáde wá, wọ́n ni ìyọnu méje náà, a wọ̀ wọ́n ní aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun ti ń dán, a sì fi àmùrè wúrà dìwọ́n ni oókan àyà. 7Àti ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà fi ìgò wúrà méje fún àwọn angẹli méje náà, tí ó kún fún ìbínú Ọlọ́run, ẹni tí ń bẹ láààyè láé àti láéláé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.