Native Bible

Revelation 15:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àti ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà fi ìgò wúrà méje fún àwọn angẹli méje náà, tí ó kún fún ìbínú Ọlọ́run, ẹni tí ń bẹ láààyè láé àti láéláé.

Revelation 15:7 in English

Revelation 15:7 · Berean Standard Bible

Then one of the four living creatures gave the seven angels seven golden bowls full of the wrath of God, who lives forever and ever.

Context

5Lẹ́yìn náà mo sì wo, sì kíyèsi i, a ṣí tẹmpili àgọ́ ẹ̀rí ní ọ̀run sílẹ̀; 6àwọn angẹli méje náà sì ti inú tẹmpili jáde wá, wọ́n ni ìyọnu méje náà, a wọ̀ wọ́n ní aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun ti ń dán, a sì fi àmùrè wúrà dìwọ́n ni oókan àyà. 7Àti ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà fi ìgò wúrà méje fún àwọn angẹli méje náà, tí ó kún fún ìbínú Ọlọ́run, ẹni tí ń bẹ láààyè láé àti láéláé. 8Tẹmpili náà sì kún fún èéfín láti inú ògo Ọlọ́run àti agbára rẹ̀ wá; ẹnikẹ́ni kò sì lè wọ inú tẹmpili náà lọ títí a fi mú ìyọnu méjèèje àwọn angẹli méje náà ṣẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.