Ìfihàn 15:4
Revelation 15:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ta ni kì yóò bẹ̀rù, Olúwa, tí kì yóò sì fi ògo fún orúkọ rẹ̀? Nítorí ìwọ nìkan ṣoṣo ni mímọ́. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni yóò sì wá, ti yóò sì foríbalẹ̀ níwájú rẹ, nítorí a ti fi ìdájọ́ rẹ hàn.”
Revelation 15:4 in English
Revelation 15:4 · Berean Standard Bible
Who will not fear You, O Lord, and glorify Your name? For You alone are holy. All nations will come and worship before You, for Your righteous acts have been revealed.”
Context
2Mo sì rí bí ẹni pé, Òkun dígí tí o dàpọ̀ pẹ̀lú iná: àwọn tí ó sì dúró lórí Òkun dígí yìí jẹ́ àwọn ti wọ́n ṣẹ́gun ẹranko náà, àti àwòrán rẹ̀, àti àmì rẹ̀ àti nọ́mbà orúkọ rẹ̀, wọn ní ohun èlò orin Ọlọ́run. 3Wọ́n sì ń kọ orin ti Mose, ìránṣẹ́ Ọlọ́run, àti orin ti Ọ̀dọ́-Àgùntàn, wí pé:
“Títóbi àti ìyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ,
Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè;
òdodo àti òtítọ́ ni ọ̀nà rẹ̀,
ìwọ ọba àwọn orílẹ̀-èdè. 4Ta ni kì yóò bẹ̀rù, Olúwa,
tí kì yóò sì fi ògo fún orúkọ rẹ̀?
Nítorí ìwọ nìkan ṣoṣo ni mímọ́.
Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni yóò sì wá,
ti yóò sì foríbalẹ̀ níwájú rẹ,
nítorí a ti fi ìdájọ́ rẹ hàn.” 5Lẹ́yìn náà mo sì wo, sì kíyèsi i, a ṣí tẹmpili àgọ́ ẹ̀rí ní ọ̀run sílẹ̀; 6àwọn angẹli méje náà sì ti inú tẹmpili jáde wá, wọ́n ni ìyọnu méje náà, a wọ̀ wọ́n ní aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun ti ń dán, a sì fi àmùrè wúrà dìwọ́n ni oókan àyà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.