Native Bible

Psalms 90:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí a tó bí àwọn òkè ńlá àti kí ìwọ tó dá ilẹ̀ àti ayé, láti ayérayé dé ayérayé ìwọ ni Ọlọ́run.

Psalms 90:2 in English

Psalms 90:2 · Berean Standard Bible

Before the mountains were born or You brought forth the earth and the world, from everlasting to everlasting You are God.

Context

1Olúwa, ìwọ ti jẹ́ ibùgbé wa ní gbogbo ìran dé ìran. 2Kí a tó bí àwọn òkè ńlá àti kí ìwọ tó dá ilẹ̀ àti ayé, láti ayérayé dé ayérayé ìwọ ni Ọlọ́run. 3Ìwọ yí ènìyàn padà sí erùpẹ̀, wí pé, “Padà sí erùpẹ̀, ìwọ ọmọ ènìyàn.” 4Nítorí pé ìgbà tí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún bá kọjá lójú rẹ, bí àná ni ó rí, bí ìgbà ìṣọ́ kan lóru.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.