Native Bible

Psalms 9:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa, wo bí àwọn ọ̀tá ṣe ń ṣe inúnibíni sí mi! Ṣàánú, kí o sì gbé mí sókè kúrò ní ẹnu-ọ̀nà ikú,

Psalms 9:13 in English

Psalms 9:13 · Berean Standard Bible

Be merciful to me, O LORD; see how my enemies afflict me! Lift me up from the gates of death,

Context

11Kọ orin ìyìn sí Olúwa, tí o ń jẹ ọba ní Sioni; kéde láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ohun tí ó ṣe. 12Nítorí ẹni tí ó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ rántí; òun kò kọ ẹkún àwọn tí a pọ́n lójú. 13Olúwa, wo bí àwọn ọ̀tá ṣe ń ṣe inúnibíni sí mi! Ṣàánú, kí o sì gbé mí sókè kúrò ní ẹnu-ọ̀nà ikú, 14kí èmi kí ó lè sọ ti ìyìn rẹ ni ẹnu-ọ̀nà àwọn ọmọbìnrin Sioni àti láti máa yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ. 15Àwọn orílẹ̀-èdè ti jì sí kòtò tí wọn ti gbẹ́; ẹsẹ̀ wọn ni àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀ kọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.