Saamu 89:47
Psalms 89:47 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Rántí bí ọjọ́ mi ti kúrú tó nítorí asán ha ni ìwọ fi ṣẹ̀dá àwọn ènìyàn!
Psalms 89:47 in English
Psalms 89:47 · Berean Standard Bible
Remember the briefness of my lifespan! For what futility You have created all men!
Context
45Ìwọ ti gé ọjọ́ èwe rẹ̀ kúrú;
ìwọ sì fi ìtìjú bò ó. 46Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa?
Tí ìwọ ó ha fi ara rẹ pamọ́ títí láé?
Yóò ti pẹ́ to tí ìbínú rẹ yóò máa jó bí iná? 47Rántí bí ọjọ́ mi ti kúrú tó
nítorí asán ha ni ìwọ fi ṣẹ̀dá àwọn ènìyàn! 48Ta ni yóò wà láààyè tí kò ní rí ikú rẹ̀?
Ta ló lè sá kúrò nínú agbára isà òkú? 49Olúwa, níbo ni ìṣeun ìfẹ́ rẹ àtijọ́ wà,
tí ìwọ ti fi òtítọ́ rẹ búra fún Dafidi?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.