Native Bible

Psalms 89:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìgbà gbogbo ni ọwọ́ mi yóò máa wà pẹ̀lú rẹ̀ apá mí yóò sì fi agbára fún un.

Psalms 89:21 in English

Psalms 89:21 · Berean Standard Bible

My hand will sustain him; surely My arm will strengthen him.

Context

19Nígbà náà ni ìwọ sọ̀rọ̀ nínú ìran, sí àwọn olóòtítọ́ rẹ, wí pé, “Èmi ti gbé adé kalẹ̀ sórí ẹni tí ó lágbára, èmi ti gbé ẹni tí a yàn láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ga. 20Èmi ti rí Dafidi ìránṣẹ́ mi; pẹ̀lú òróró mímọ́ mi ni mo fi yàn án. 21Ìgbà gbogbo ni ọwọ́ mi yóò máa wà pẹ̀lú rẹ̀ apá mí yóò sì fi agbára fún un. 22Àwọn ọ̀tá kì yóò borí rẹ̀, àwọn ènìyàn búburú kì yóò rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀. 23Èmi yóò run àwọn ọ̀tá rẹ níwájú rẹ èmi yóò lu àwọn tí ó kórìíra rẹ bolẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.