Native Bible

Psalms 89:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni ìwọ sọ̀rọ̀ nínú ìran, sí àwọn olóòtítọ́ rẹ, wí pé, “Èmi ti gbé adé kalẹ̀ sórí ẹni tí ó lágbára, èmi ti gbé ẹni tí a yàn láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ga.

Psalms 89:19 in English

Psalms 89:19 · Berean Standard Bible

You once spoke in a vision; to Your godly ones You said, “I have bestowed help on a warrior; I have exalted one chosen from the people.

Context

17Nítorí ìwọ ni ògo agbára wọn; nípa ojúrere ni ìwo wá ń ṣògo. 18Nítorí ti Olúwa ni asà wa, ọba wa sì ni Ẹni Mímọ́ Israẹli. 19Nígbà náà ni ìwọ sọ̀rọ̀ nínú ìran, sí àwọn olóòtítọ́ rẹ, wí pé, “Èmi ti gbé adé kalẹ̀ sórí ẹni tí ó lágbára, èmi ti gbé ẹni tí a yàn láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ga. 20Èmi ti rí Dafidi ìránṣẹ́ mi; pẹ̀lú òróró mímọ́ mi ni mo fi yàn án. 21Ìgbà gbogbo ni ọwọ́ mi yóò máa wà pẹ̀lú rẹ̀ apá mí yóò sì fi agbára fún un.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.