Saamu 89:18
Psalms 89:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí ti Olúwa ni asà wa, ọba wa sì ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.
Psalms 89:18 in English
Psalms 89:18 · Berean Standard Bible
Surely our shield belongs to the LORD, and our king to the Holy One of Israel.
Context
16Wọn ń ṣògo nínú orúkọ rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́,
wọn ń yin òdodo rẹ. 17Nítorí ìwọ ni ògo agbára wọn;
nípa ojúrere ni ìwo wá ń ṣògo. 18Nítorí ti Olúwa ni asà wa,
ọba wa sì ni Ẹni Mímọ́ Israẹli. 19Nígbà náà ni ìwọ sọ̀rọ̀ nínú ìran, sí àwọn olóòtítọ́ rẹ, wí pé,
“Èmi ti gbé adé kalẹ̀ sórí ẹni tí ó lágbára,
èmi ti gbé ẹni tí a yàn láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ga. 20Èmi ti rí Dafidi ìránṣẹ́ mi;
pẹ̀lú òróró mímọ́ mi ni mo fi yàn án.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.