Saamu 74:9
Psalms 74:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
A kò fún wa ní àmì iṣẹ́ ìyanu kankan; kò sí wòlíì kankan ẹnìkankan wa kò mọ ìgbà tí eléyìí yóò dà.
Psalms 74:9 in English
Psalms 74:9 · Berean Standard Bible
There are no signs for us to see. There is no longer any prophet. And none of us knows how long this will last.
Context
7Wọ́n sun ibi mímọ́ rẹ lulẹ̀
wọ́n ba ibùgbé orúkọ rẹ jẹ́. 8Wọ́n wí ní ọkàn wọn. “Àwa ó run wọ́n pátápátá!”
Wọ́n sun gbogbo ibi ìjọ́sìn Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà. 9A kò fún wa ní àmì iṣẹ́ ìyanu kankan;
kò sí wòlíì kankan
ẹnìkankan wa kò mọ ìgbà tí eléyìí yóò dà. 10Àwọn ọ̀tá yóò ti kùn sí ọ pẹ́ tó, Ọlọ́run?
Àwọn ọ̀tá yóò ha ba orúkọ rẹ jẹ́ títí láé? 11Èéṣe tí ìwọ fi dá ọwọ́ rẹ dúró, ọwọ́ ọ̀tún rẹ?
Mú un kúrò nínú ìṣẹ́po aṣọ rẹ kí o sì run wọ́n!
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.