Saamu 72:4
Psalms 72:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Yóò dáàbò bo àwọn tí a pọ́n lójú láàrín àwọn ènìyàn yóò gba àwọn ọmọ aláìní; yóò sì fa àwọn aninilára ya.
Psalms 72:4 in English
Psalms 72:4 · Berean Standard Bible
May he vindicate the afflicted among the people; may he save the children of the needy and crush the oppressor.
Context
2Yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú òdodo,
yóò sì máa fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn tálákà rẹ̀. 3Àwọn òkè ńlá yóò máa mú àlàáfíà fún àwọn ènìyàn
àti òkè kéékèèké nípa òdodo. 4Yóò dáàbò bo àwọn tí a pọ́n lójú láàrín àwọn ènìyàn
yóò gba àwọn ọmọ aláìní;
yóò sì fa àwọn aninilára ya. 5Àwọn òtòṣì àti aláìní
yóò máa fi ọ̀wọ̀ ńlá fún ọ nígbà gbogbo,
níwọ̀n ìgbà tí oòrùn àti òṣùpá bá ń ràn,
yóò ti pẹ́ tó, láti ìrandíran. 6Yóò dàbí òjò tí ó ń rọ̀ sórí pápá ìrẹ́mọ́lẹ̀,
bí ọwọ́ òjò tó ń rin ilẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.