Native Bible

Psalms 72:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn òkè ńlá yóò máa mú àlàáfíà fún àwọn ènìyàn àti òkè kéékèèké nípa òdodo.

Psalms 72:3 in English

Psalms 72:3 · Berean Standard Bible

May the mountains bring peace to the people, and the hills bring righteousness.

Context

1Fi ìdájọ́ fún àwọn ọba, Ọlọ́run, ọmọ-aládé ni ìwọ fi òdodo rẹ fún. 2Yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú òdodo, yóò sì máa fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn tálákà rẹ̀. 3Àwọn òkè ńlá yóò máa mú àlàáfíà fún àwọn ènìyàn àti òkè kéékèèké nípa òdodo. 4Yóò dáàbò bo àwọn tí a pọ́n lójú láàrín àwọn ènìyàn yóò gba àwọn ọmọ aláìní; yóò sì fa àwọn aninilára ya. 5Àwọn òtòṣì àti aláìní yóò máa fi ọ̀wọ̀ ńlá fún ọ nígbà gbogbo, níwọ̀n ìgbà tí oòrùn àti òṣùpá bá ń ràn, yóò ti pẹ́ tó, láti ìrandíran.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.