Native Bible

Psalms 71:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Má ṣe ta mí nù ní ọjọ́ ogbó mi, má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ nígbà tí kò sí okun mọ́.

Psalms 71:9 in English

Psalms 71:9 · Berean Standard Bible

Do not discard me in my old age; do not forsake me when my strength fails.

Context

7Mo di àmì fún ọ̀pọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára. 8Ìyìn rẹ̀ kún ẹnu mi, ó ń sọ ti ọlá rẹ ní ọjọ́ gbogbo. 9Má ṣe ta mí nù ní ọjọ́ ogbó mi, má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ nígbà tí kò sí okun mọ́. 10Nítorí àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀-òdì sí mi, àwọn tí wọn dúró láti pa mí gbìmọ̀ pọ̀. 11Wọ́n wí pé, “Ọlọ́run ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀; lépa rẹ̀ kí ẹ sì mu, nítorí kò sí ẹni tí yóò gbà á.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.