Native Bible

Psalms 68:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Pàṣẹ agbára rẹ, Ọlọ́run; fi agbára rẹ hàn wá, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe ní ìṣáájú.

Psalms 68:28 in English

Psalms 68:28 · Berean Standard Bible

Summon Your power, O God;* show Your strength, O God, which You have exerted on our behalf.

Context

26Ẹ fi ìyìn fún Olúwa ní ẹgbẹgbẹ́; àní fún Olúwa ẹ̀yin tí ó ti orísun Israẹli wá. 27Níbẹ̀ ní ẹ̀yà kékeré Benjamini wà, tí ó ń darí wọn, níbẹ̀ ni àwọn ọmọ-aládé Juda, níbẹ̀ ni àwọn ọmọ-aládé Sebuluni àti tí Naftali. 28Pàṣẹ agbára rẹ, Ọlọ́run; fi agbára rẹ hàn wá, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe ní ìṣáájú. 29Nítorí tẹmpili rẹ ni Jerusalẹmu àwọn ọba yóò mú ẹ̀bùn wá fún ọ. 30Bá àwọn ẹranko búburú wí, tí ń gbé láàrín eèsún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akọ màlúù pẹ̀lú àwọn ọmọ màlúù títí olúkúlùkù yóò fi foríbalẹ̀ pẹ̀lú ìwọ̀n fàdákà: tú àwọn ènìyàn tí ń ṣe inú dídùn sí ogun ká.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.