Native Bible

Psalms 65:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn tí ó ń gbé òkèrè bẹ̀rù, nítorí àmì rẹ wọ̀n-ọn-nì; ìwọ mú ìjáde òwúrọ̀ àti ti àṣálẹ́ yọ̀, ìwọ pè fún orin ayọ̀.

Psalms 65:8 in English

Psalms 65:8 · Berean Standard Bible

Those who live far away fear Your wonders; You make the dawn and sunset shout for joy.*

Context

6ìwọ tí ó dá òkè nípa agbára rẹ, tí odi ara rẹ ní àmùrè agbára, 7ẹni tí ó mú rírú omi òkun dákẹ́, ríru ariwo omi wọn, àti ìdágìrì àwọn ènìyàn. 8Àwọn tí ó ń gbé òkèrè bẹ̀rù, nítorí àmì rẹ wọ̀n-ọn-nì; ìwọ mú ìjáde òwúrọ̀ àti ti àṣálẹ́ yọ̀, ìwọ pè fún orin ayọ̀. 9Ìwọ bẹ ayé wò, o sì bomirin; ìwọ mú un ọ̀rọ̀ púpọ̀. Odò Ọlọ́run kún fún omi láti pèsè ọkà fún àwọn ènìyàn, nítorí ibẹ̀ ni ìwọ ti yàn án. 10Ìwọ fi bomirin sí aporo rẹ̀ ìwọ tẹ́ ògúlùtu rẹ̀; ìwọ fi òjò mú ilẹ̀ rẹ̀ rọ̀, o sì bùkún ọ̀gbìn rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.