Saamu 65:6
Psalms 65:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
ìwọ tí ó dá òkè nípa agbára rẹ, tí odi ara rẹ ní àmùrè agbára,
Psalms 65:6 in English
Psalms 65:6 · Berean Standard Bible
You formed the mountains by Your power, having girded Yourself with might.
Context
4Ìbùkún ni fún àwọn tí o yàn
tí o mú wa láti máa gbé àgọ́ rẹ!
A tẹ́ wá lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere inú ilé rẹ,
ti tẹmpili mímọ́ rẹ. 5Ìwọ dá wa lóhùn pẹ̀lú ohun ìyanu ti òdodo,
Ọlọ́run olùgbàlà wa,
ẹni tí ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé gbogbo òpin ayé
àti àwọn tí ó jìnnà nínú òkun, 6ìwọ tí ó dá òkè nípa agbára rẹ,
tí odi ara rẹ ní àmùrè agbára, 7ẹni tí ó mú rírú omi òkun dákẹ́,
ríru ariwo omi wọn,
àti ìdágìrì àwọn ènìyàn. 8Àwọn tí ó ń gbé òkèrè bẹ̀rù,
nítorí àmì rẹ wọ̀n-ọn-nì;
ìwọ mú ìjáde òwúrọ̀ àti ti àṣálẹ́ yọ̀,
ìwọ pè fún orin ayọ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.