Native Bible

Psalms 65:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ tí ó ń gbọ́ àdúrà, gbogbo ènìyàn yóò sì wá sọ́dọ̀ rẹ.

Psalms 65:2 in English

Psalms 65:2 · Berean Standard Bible

O You who listen to prayer, all people will come to You.

Context

1Ìyìn ń dúró dè ọ́, Ọlọ́run, ní Sioni; sí ọ ni a ó mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ. 2Ìwọ tí ó ń gbọ́ àdúrà, gbogbo ènìyàn yóò sì wá sọ́dọ̀ rẹ. 3Ọ̀ràn àìṣedéédéé borí mi bí ó ṣe ti ìrékọjá wa ni! Ìwọ ni yóò wẹ̀ wọ́n nù kúrò. 4Ìbùkún ni fún àwọn tí o yàn tí o mú wa láti máa gbé àgọ́ rẹ! A tẹ́ wá lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere inú ilé rẹ, ti tẹmpili mímọ́ rẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.