Native Bible

Psalms 65:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ fi oore rẹ dé ọdún ní adé, ọ̀rá ń kán ní ipa ọ̀nà rẹ.

Psalms 65:11 in English

Psalms 65:11 · Berean Standard Bible

You crown the year with Your bounty, and Your paths overflow with plenty.

Context

9Ìwọ bẹ ayé wò, o sì bomirin; ìwọ mú un ọ̀rọ̀ púpọ̀. Odò Ọlọ́run kún fún omi láti pèsè ọkà fún àwọn ènìyàn, nítorí ibẹ̀ ni ìwọ ti yàn án. 10Ìwọ fi bomirin sí aporo rẹ̀ ìwọ tẹ́ ògúlùtu rẹ̀; ìwọ fi òjò mú ilẹ̀ rẹ̀ rọ̀, o sì bùkún ọ̀gbìn rẹ̀. 11Ìwọ fi oore rẹ dé ọdún ní adé, ọ̀rá ń kán ní ipa ọ̀nà rẹ. 12Pápá tútù ní aginjù ń kan àwọn òkè kéékèèké fi ayọ̀ di ara wọn ní àmùrè. 13Agbo ẹran ni a fi wọ pápá tútù náà ní aṣọ; àfonífojì ni a fi ọkà bò mọ́lẹ̀, wọ́n hó fún ayọ̀, wọ́n ń kọrin pẹ̀lú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.