Saamu 59:4
Psalms 59:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi kò ṣe àìṣedéédéé kan, síbẹ̀ wọ́n sáré wọ́n ṣetán láti kọlù mí. Dìde fún ìrànlọ́wọ́ mi, kí o sì wo àìlera mi.
Psalms 59:4 in English
Psalms 59:4 · Berean Standard Bible
For no fault of my own, they move swiftly to attack me. Arise to help me, and take notice.
Context
2Gbà mí lọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ búburú
kí o sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ènìyàn tí ń pòǹgbẹ ẹ̀jẹ̀. 3Wò ó, bí wọ́n ṣe ba ní bùba dè mí!
Àwọn alágbára ń gbìmọ̀ lòdì sí mi
kì í ṣe nítorí ìrékọjá mi tàbí ẹ̀ṣẹ̀ mí, Olúwa. 4Èmi kò ṣe àìṣedéédéé kan, síbẹ̀ wọ́n sáré wọ́n ṣetán láti kọlù mí.
Dìde fún ìrànlọ́wọ́ mi, kí o sì wo àìlera mi. 5Olúwa Ọlọ́run Alágbára,
Ọlọ́run Israẹli,
dìde fún ara rẹ kí o sì bá àwọn orílẹ̀-èdè wí;
má ṣe ṣàánú fún àwọn olùrékọjá búburú nì. Sela. 6Wọ́n padà ní àṣálẹ́,
wọ́n ń gbó bí àwọn ajá,
wọ́n ń rìn yí ìlú náà káàkiri.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.