Saamu 59:6
Psalms 59:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n padà ní àṣálẹ́, wọ́n ń gbó bí àwọn ajá, wọ́n ń rìn yí ìlú náà káàkiri.
Psalms 59:6 in English
Psalms 59:6 · Berean Standard Bible
They return in the evening, snarling like dogs and prowling around the city.
Context
4Èmi kò ṣe àìṣedéédéé kan, síbẹ̀ wọ́n sáré wọ́n ṣetán láti kọlù mí.
Dìde fún ìrànlọ́wọ́ mi, kí o sì wo àìlera mi. 5Olúwa Ọlọ́run Alágbára,
Ọlọ́run Israẹli,
dìde fún ara rẹ kí o sì bá àwọn orílẹ̀-èdè wí;
má ṣe ṣàánú fún àwọn olùrékọjá búburú nì. Sela. 6Wọ́n padà ní àṣálẹ́,
wọ́n ń gbó bí àwọn ajá,
wọ́n ń rìn yí ìlú náà káàkiri. 7Kíyèsi ohun tí wọ́n tú jáde ní ẹnu:
wọn ń tú idà jáde láti ètè wọn,
wọ́n sì wí pé, “Ta ni ó lè gbọ́ ọ̀rọ̀ wa?” 8Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, yóò fi wọ́n rẹ́rìn-ín,
Ìwọ ó yọ ṣùtì sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.