Native Bible

Psalms 37:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi ti wà ni èwe, báyìí èmi sì dàgbà; síbẹ̀ èmi kò ì tí ì ri kí a kọ olódodo sílẹ̀, tàbí kí irú-ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe oúnjẹ.

Psalms 37:25 in English

Psalms 37:25 · Berean Standard Bible

I once was young and now am old, yet never have I seen the righteous abandoned or their children begging for bread.

Context

23Ìlànà ìgbésẹ̀ ènìyàn rere wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá, o sì ṣe inú dídùn sí ọ̀nà rẹ̀; 24bí ó tilẹ̀ ṣubú a kì yóò ta á nù pátápátá, nítorí tí Olúwa di ọwọ́ rẹ̀ mú. 25Èmi ti wà ni èwe, báyìí èmi sì dàgbà; síbẹ̀ èmi kò ì tí ì ri kí a kọ olódodo sílẹ̀, tàbí kí irú-ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe oúnjẹ. 26Aláàánú ni òun nígbà gbogbo a máa yá ni; a sì máa bùsi i fún ni. 27Lọ kúrò nínú ibi, kí o sì máa ṣe rere; nígbà náà ni ìwọ yóò gbé ní ilẹ̀ náà títí láéláé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.