Native Bible

Psalms 37:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

bí ó tilẹ̀ ṣubú a kì yóò ta á nù pátápátá, nítorí tí Olúwa di ọwọ́ rẹ̀ mú.

Psalms 37:24 in English

Psalms 37:24 · Berean Standard Bible

Though he falls, he will not be overwhelmed, for the LORD is holding his hand.*

Context

22nítorí àwọn tí Olúwa bá bùkún ni yóò jogún ilẹ̀ náà, àwọn tí ó fi bú ni a ó gé kúrò. 23Ìlànà ìgbésẹ̀ ènìyàn rere wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá, o sì ṣe inú dídùn sí ọ̀nà rẹ̀; 24bí ó tilẹ̀ ṣubú a kì yóò ta á nù pátápátá, nítorí tí Olúwa di ọwọ́ rẹ̀ mú. 25Èmi ti wà ni èwe, báyìí èmi sì dàgbà; síbẹ̀ èmi kò ì tí ì ri kí a kọ olódodo sílẹ̀, tàbí kí irú-ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe oúnjẹ. 26Aláàánú ni òun nígbà gbogbo a máa yá ni; a sì máa bùsi i fún ni.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.