Native Bible

Psalms 37:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ènìyàn búburú di rìkíṣí sí olóòtítọ́, wọ́n sì pa eyín wọn keke sí wọn;

Psalms 37:12 in English

Psalms 37:12 · Berean Standard Bible

The wicked scheme against the righteous and gnash their teeth at them,

Context

10Síbẹ̀ nígbà díẹ̀ sí i, àwọn ènìyàn búburú kì yóò sí mọ̀; nítòótọ́ ìwọ yóò fi ara balẹ̀ wo ipò rẹ̀, wọn kì yóò sí níbẹ̀. 11Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò jogún ilẹ̀ náà, wọn yóò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà. 12Ènìyàn búburú di rìkíṣí sí olóòtítọ́, wọ́n sì pa eyín wọn keke sí wọn; 13ṣùgbọ́n Olúwa rẹ́rìn-ín sí àwọn ènìyàn búburú, nítorí tí ó rí wí pé ọjọ́ wọn ń bọ̀. 14Ènìyàn búburú fa idà yọ, wọ́n sì tẹ àwọn ọrun wọn, láti sọ tálákà àti aláìní kalẹ̀, láti pa àwọn tí ó dúró ṣinṣin.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.