Saamu 37:11
Psalms 37:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò jogún ilẹ̀ náà, wọn yóò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.
Psalms 37:11 in English
Psalms 37:11 · Berean Standard Bible
But the meek will inherit the land * and delight in abundant prosperity.
Context
9Nítorí tí á ó gé àwọn olùṣe búburú kúrò,
ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá dúró de Olúwa àwọn ni yóò jogún ilẹ̀ náà. 10Síbẹ̀ nígbà díẹ̀ sí i, àwọn ènìyàn búburú kì yóò sí mọ̀;
nítòótọ́ ìwọ yóò fi ara balẹ̀ wo ipò rẹ̀, wọn kì yóò sí níbẹ̀. 11Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò jogún ilẹ̀ náà,
wọn yóò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà. 12Ènìyàn búburú di rìkíṣí sí olóòtítọ́,
wọ́n sì pa eyín wọn keke sí wọn; 13ṣùgbọ́n Olúwa rẹ́rìn-ín sí àwọn ènìyàn búburú,
nítorí tí ó rí wí pé ọjọ́ wọn ń bọ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.