Saamu 33:15
Psalms 33:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
ẹni tí ó ṣe àyà wọn bákan náà, ó sì kíyèsi ìṣe wọn.
Psalms 33:15 in English
Psalms 33:15 · Berean Standard Bible
He shapes the hearts of each; He considers all their works.
Context
13Olúwa wò láti ọ̀run wá;
Ó sì rí gbogbo ìran ènìyàn. 14Níbi tí ó ti jókòó lórí ìtẹ́
Ó wo gbogbo àwọn olùgbé ayé 15ẹni tí ó ṣe àyà wọn bákan náà,
ó sì kíyèsi ìṣe wọn. 16A kò gba ọba kan là nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ogun;
kò sì sí jagunjagun tí a gbà sílẹ̀ nípa agbára ńlá rẹ̀. 17Ohun asán ni ẹṣin fún ìṣẹ́gun;
bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi agbára ńlá rẹ̀ gbani sílẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.