Saamu 31:21
Psalms 31:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olùbùkún ni Olúwa, nítorí pé ó ti fi àgbà ìyanu ìfẹ́ tí ó ní sí mi hàn, nígbà tí mo wà ní ìlú tí wọ́n rọ̀gbà yíká.
Psalms 31:21 in English
Psalms 31:21 · Berean Standard Bible
Blessed be the LORD, for He has shown me His loving devotion in a city under siege.
Context
19Báwo ni títóbi oore rẹ̀ ti pọ̀ tó,
èyí tí ìwọ ti ní ní ìpamọ́ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,
èyí tí ìwọ rọ̀jò rẹ̀ níwájú àwọn ènìyàn
tí wọ́n fi ọ́ ṣe ibi ìsádi wọn. 20Ní abẹ́ ìbòòji iwájú rẹ ni ìwọ pa wọ́n mọ́ sí
kúrò nínú ìdìmọ̀lù àwọn ènìyàn;
ní ibùgbé rẹ, o mú wọn kúrò nínú ewu
kúrò nínú ìjà ahọ́n. 21Olùbùkún ni Olúwa,
nítorí pé ó ti fi àgbà ìyanu ìfẹ́ tí ó ní sí mi hàn,
nígbà tí mo wà ní ìlú tí wọ́n rọ̀gbà yíká. 22Èmí ti sọ nínú ìdágìrì mi,
“A gé mi kúrò ní ojú rẹ!”
Síbẹ̀ ìwọ ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú
nígbà tí mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́. 23Ẹ fẹ́ Olúwa, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́!
Olúwa pa olódodo mọ́,
ó sì san án padà fún agbéraga ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.